Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A kò ní mú òkúta kankan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di ahoro títí ayé,” ní Olúwa wí.

Jeremiah 51:26 in English

Jeremiah 51:26 · Berean Standard Bible

No one shall retrieve from you a cornerstone or a foundation stone, because you will become desolate forever,” declares the LORD.

Context

24“Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Babeli àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Sioni,” ni Olúwa wí. 25“Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,” ni Olúwa wí. “Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ, èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta, Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó. 26A kò ní mú òkúta kankan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di ahoro títí ayé,” ní Olúwa wí. 27“Gbé àsíá sókè ní ilẹ̀ náà! Fọn ìpè láàrín àwọn orílẹ̀-èdè! Sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́ sórí rẹ̀, pe àwọn ìjọba yìí láti dojúkọ ọ́: Ararati, Minini àti Aṣkenasi. Yan olùdarí ogun láti kọlù ú, rán àwọn ẹṣin sí i bí ọ̀pọ̀ eṣú. 28Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀, àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.