Jeremiah 51:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Asán ni wọ́n, àti iṣẹ́ ìsìnà, nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn ó ṣègbé.
Jeremiah 51:18 in English
Jeremiah 51:18 · Berean Standard Bible
They are worthless, a work to be mocked. In the time of their punishment they will perish.
Context
16Nígbà tí ará omi ọ̀run hó
ó mú kí òfúrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé.
Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,
ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀. 17“Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọ tí kò sì ní ìmọ̀,
olúkúlùkù alágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀.
Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn;
wọn kò ní èémí nínú. 18Asán ni wọ́n, àti iṣẹ́ ìsìnà,
nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn ó ṣègbé. 19Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jakọbu kó rí bí ìwọ̀nyí;
nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo,
àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 20“Ìwọ ni kùmọ̀ ogun ohun èlò ogun mi,
ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀-èdè túútúú,
èmi ó bà àwọn ilé ọba jẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.