Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jakọbu kó rí bí ìwọ̀nyí; nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo, àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

Jeremiah 51:19 in English

Jeremiah 51:19 · Berean Standard Bible

The Portion of Jacob is not like these, for He is the Maker of all things, and of the tribe of His inheritance— the LORD of Hosts is His name.

Context

17“Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọ tí kò sì ní ìmọ̀, olúkúlùkù alágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀. Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn; wọn kò ní èémí nínú. 18Asán ni wọ́n, àti iṣẹ́ ìsìnà, nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn ó ṣègbé. 19Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jakọbu kó rí bí ìwọ̀nyí; nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo, àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 20“Ìwọ ni kùmọ̀ ogun ohun èlò ogun mi, ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀-èdè túútúú, èmi ó bà àwọn ilé ọba jẹ́. 21Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀; èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lú èmi ó pa awakọ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.