Jeremiah 51:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìwọ ni kùmọ̀ ogun ohun èlò ogun mi, ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀-èdè túútúú, èmi ó bà àwọn ilé ọba jẹ́.
Jeremiah 51:20 in English
Jeremiah 51:20 · Berean Standard Bible
“You are My war club, My weapon for battle. With you I shatter nations; with you I bring kingdoms to ruin.
Context
18Asán ni wọ́n, àti iṣẹ́ ìsìnà,
nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn ó ṣègbé. 19Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jakọbu kó rí bí ìwọ̀nyí;
nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo,
àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 20“Ìwọ ni kùmọ̀ ogun ohun èlò ogun mi,
ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀-èdè túútúú,
èmi ó bà àwọn ilé ọba jẹ́. 21Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀;
èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lú
èmi ó pa awakọ̀, 22pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin,
pẹ̀lú rẹ, mo pa àgbàlagbà àti ọmọdé,
pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.