Jeremiah 50:30
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́,” ní Olúwa wí.
Jeremiah 50:30 in English
Jeremiah 50:30 · Berean Standard Bible
Therefore, her young men will fall in the streets, and all her warriors will be silenced in that day,” declares the LORD.
Context
28Gbọ́ ohùn àwọn tí ó sálọ, tí ó sì sálà láti Babeli wá,
sì sọ ní Sioni,
bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san,
ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀. 29“Pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Babeli,
ẹ dó tí ì yíkákiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà.
Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀
gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ó ti ṣe,
ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, nítorí tí ó ti gbéraga
sí Olúwa, sí Ẹni Mímọ́ Israẹli. 30Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀
yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn
ológun lẹ́nu mọ́,”
ní Olúwa wí. 31“Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,”
ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“nítorí ọjọ́ rẹ ti dé,
àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò. 32Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú,
kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde.
Èmi yóò tan iná ní ìlú náà,
èyí tí yóò sì jo run.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.