Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “nítorí ọjọ́ rẹ ti dé, àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò.

Jeremiah 50:31 in English

Jeremiah 50:31 · Berean Standard Bible

“Behold, I am against you, O arrogant one,” declares the Lord GOD of Hosts, “for your day has come, the time when I will punish you.

Context

29“Pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Babeli, ẹ dó tí ì yíkákiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà. Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ó ti ṣe, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, nítorí tí ó ti gbéraga sí Olúwa, sí Ẹni Mímọ́ Israẹli. 30Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́,” ní Olúwa wí. 31“Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “nítorí ọjọ́ rẹ ti dé, àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò. 32Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde. Èmi yóò tan iná ní ìlú náà, èyí tí yóò sì jo run.” 33Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “A pọ́n àwọn ènìyàn Israẹli lójú àti àwọn ènìyàn Juda pẹ̀lú. Gbogbo àwọn tí ó kó wọn nígbèkùn dì wọn mú ṣinṣin wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.