Jeremiah 5:23
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀, wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.
Jeremiah 5:23 in English
Jeremiah 5:23 · Berean Standard Bible
But these people have stubborn and rebellious hearts. They have turned aside and gone away.
Context
21Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn,
tí ó lójú ti kò fi ríran
tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀. 22Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?”
ni Olúwa wí.
“Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí?
Mo fi yanrìn pààlà òkun,
èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.
Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;
wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀. 23Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,
wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ. 24Wọn kò sọ fún ara wọn pé,
‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,
ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,
tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’ 25Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,
ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.