Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn kò sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀, tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’

Jeremiah 5:24 in English

Jeremiah 5:24 · Berean Standard Bible

They have not said in their hearts, ‘Let us fear the LORD our God, who gives the rains, both autumn and spring, in season, who keeps for us the appointed weeks of harvest.’

Context

22Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí. “Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí? Mo fi yanrìn pààlà òkun, èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé. Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀; wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀. 23Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀, wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ. 24Wọn kò sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀, tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’ 25Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín. 26“Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ, àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.