Jeremiah 5:26
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ, àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.
Jeremiah 5:26 in English
Jeremiah 5:26 · Berean Standard Bible
For among My people are wicked men; they watch like fowlers lying in wait; they set a trap to catch men.
Context
24Wọn kò sọ fún ara wọn pé,
‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,
ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,
tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’ 25Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,
ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín. 26“Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà
tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ,
àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn. 27Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ,
ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn;
wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára, 28wọ́n sanra wọ́n sì ń dán.
Ìwà búburú wọn kò sì lópin;
wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀.
Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.