Jeremiah 5:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn, tí ó lójú ti kò fi ríran tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.
Jeremiah 5:21 in English
Jeremiah 5:21 · Berean Standard Bible
“Hear this, O foolish and senseless people, who have eyes but do not see, who have ears but do not hear.
Context
19Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsin yìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.’ 20“Kéde èyí fún ilé Jakọbu,
kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda. 21Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn,
tí ó lójú ti kò fi ríran
tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀. 22Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?”
ni Olúwa wí.
“Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí?
Mo fi yanrìn pààlà òkun,
èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.
Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;
wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀. 23Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,
wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.