Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kéde èyí fún ilé Jakọbu, kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda.

Jeremiah 5:20 in English

Jeremiah 5:20 · Berean Standard Bible

Declare this in the house of Jacob and proclaim it in Judah:

Context

18“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátápátá. 19Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsin yìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.’ 20“Kéde èyí fún ilé Jakọbu, kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda. 21Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn, tí ó lójú ti kò fi ríran tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀. 22Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí. “Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí? Mo fi yanrìn pààlà òkun, èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé. Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀; wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.