Jeremiah 49:27
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi yóò fi iná sí odi Damasku, yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”
Jeremiah 49:27 in English
Jeremiah 49:27 · Berean Standard Bible
“I will set fire to the walls of Damascus; it will consume the fortresses of Ben-hadad.”
Context
25Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀;
ìlú tí mo dunnú sí. 26Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó,
gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,”
ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 27“Èmi yóò fi iná sí odi Damasku,
yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.” 28Nípa ìlú Kedari àti ìjọba Hasori èyí ti Nebukadnessari ọba Babeli dojú ìjà kọ,
èyí ni ohun tí Olúwa sọ,
“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ ìlú Kedari,
kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn run. 29Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọn ni wọn ó kó lọ;
àgọ́ wọn yóò di ìṣínípò padà
pẹ̀lú gbogbo ẹrù àti ìbákasẹ wọn.
Àwọn ènìyàn yóò ké sórí wọ́n pé,
‘Ẹ̀rù yí káàkiri!’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.