Jeremiah 49:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀; ìlú tí mo dunnú sí.
Jeremiah 49:25 in English
Jeremiah 49:25 · Berean Standard Bible
How is the city of praise not forsaken, the town that brings Me joy?
Context
23Nípa Damasku.
“Inú Hamati àti Arpadi bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn,
wọ́n sì dààmú bí omi Òkun. 24Damasku di aláìlera,
ó pẹ̀yìndà láti sálọ,
ìwárìrì sì dé bá a;
ìbẹ̀rù àti ìrora dìímú,
ìrora bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí. 25Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀;
ìlú tí mo dunnú sí. 26Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó,
gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,”
ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 27“Èmi yóò fi iná sí odi Damasku,
yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.