Jeremiah 49:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Edomu yóò di ahoro gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ.
Jeremiah 49:17 in English
Jeremiah 49:17 · Berean Standard Bible
“Edom will become an object of horror. All who pass by will be appalled and will scoff at all her wounds.
Context
15“Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di
kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo;
ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn. 16Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú
ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ;
ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta,
tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga
síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì;
láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,”
ni Olúwa wí. 17“Edomu yóò di ahoro
gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì
fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ. 18Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu
àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú
tí ó wà ní àyíká rẹ,”
ní Olúwa wí.
“Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀;
kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́. 19“Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,
Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.
Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?
Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?
Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.