Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta, tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni Olúwa wí.

Jeremiah 49:16 in English

Jeremiah 49:16 · Berean Standard Bible

The terror you cause and the pride of your heart have deceived you, O dwellers in the clefts of the rocks,* O occupiers of the mountain summit. Though you elevate your nest like the eagle, even from there I will bring you down,” declares the LORD.

Context

14Ní gbígbọ́, èmi ti gbọ́ ìró kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, a rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀-èdè pé, ẹ kó ara yín jọ, ẹ wá sórí rẹ̀, ẹ sì dìde láti jagun. 15“Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo; ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn. 16Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta, tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni Olúwa wí. 17“Edomu yóò di ahoro gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ. 18Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ,” ní Olúwa wí. “Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀; kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.