Jeremiah 49:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò, èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn, nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́. Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti àwọn ará ilé rẹ yóò parun. Wọn kò sì ní sí mọ́.
Jeremiah 49:10 in English
Jeremiah 49:10 · Berean Standard Bible
But I will strip Esau bare; I will uncover his hiding places, and he will be unable to conceal himself. His descendants will be destroyed along with his relatives and neighbors, and he will be no more.
Context
8Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò,
ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani,
nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau,
ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò. 9Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá;
ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀?
Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní
kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́? 10Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò,
èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn,
nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́.
Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti
àwọn ará ilé rẹ yóò parun.
Wọn kò sì ní sí mọ́. 11Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀
èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn.
Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.” 12Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.