Jeremiah 49:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀ èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn. Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”
Jeremiah 49:11 in English
Jeremiah 49:11 · Berean Standard Bible
Abandon your orphans; I will preserve their lives. Let your widows trust in Me.”
Context
9Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá;
ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀?
Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní
kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́? 10Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò,
èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn,
nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́.
Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti
àwọn ará ilé rẹ yóò parun.
Wọn kò sì ní sí mọ́. 11Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀
èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn.
Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.” 12Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un. 13Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.