Jeremiah 46:28
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. “Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí. Èmi kò ní run yín tán. Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo, èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”
Jeremiah 46:28 in English
Jeremiah 46:28 · Berean Standard Bible
And you, My servant Jacob, do not be afraid, declares the LORD, for I am with you. Though I will completely destroy all the nations to which I have banished you, I will not completely destroy you. Yet I will discipline you justly, and will by no means leave you unpunished.”
Context
26Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí. 27“Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
má fòyà, ìwọ Israẹli.
Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn,
àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.
Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò,
kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á. 28Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
“Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,
láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí.
Èmi kò ní run yín tán.
Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo,
èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.