Jeremiah 46:27
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má fòyà, ìwọ Israẹli. Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò, kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á.
Jeremiah 46:27 in English
Jeremiah 46:27 · Berean Standard Bible
But you, O Jacob My servant, do not be afraid, and do not be dismayed, O Israel. For I will surely save you out of a distant place, your descendants from the land of their captivity! Jacob will return to quiet and ease, with no one to make him afraid.
Context
25Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí Amoni òrìṣà Tebesi, sórí Farao, sórí Ejibiti àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Farao. 26Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí. 27“Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
má fòyà, ìwọ Israẹli.
Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn,
àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.
Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò,
kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á. 28Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
“Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,
láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí.
Èmi kò ní run yín tán.
Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo,
èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.