Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti, a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”

Jeremiah 46:24 in English

Jeremiah 46:24 · Berean Standard Bible

The Daughter of Egypt will be put to shame; she will be delivered into the hands of the people of the north.”

Context

22Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára. Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké, gẹ́gẹ́ bí i ti agégi. 23Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,” ni Olúwa wí, “nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀. Nítorí pé wọ́n pọ̀ ju ẹlẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye. 24A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti, a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.” 25Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí Amoni òrìṣà Tebesi, sórí Farao, sórí Ejibiti àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Farao. 26Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.