Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára. Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké, gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.

Jeremiah 46:22 in English

Jeremiah 46:22 · Berean Standard Bible

Egypt will hiss like a fleeing serpent,* for the enemy will advance in force; with axes they will come against her like woodsmen cutting down trees.

Context

20“Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní Ejibiti ṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé, ó dé láti àríwá. 21Àwọn jagunjagun rẹ̀ dàbí àbọ́pa akọ màlúù. Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà, wọn ó sì jùmọ̀ sá, wọn kò ní le dúró, nítorí tí ọjọ́ ibi ń bọ̀ lórí wọn àsìkò láti jẹ wọ́n ní ìyà. 22Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára. Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké, gẹ́gẹ́ bí i ti agégi. 23Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,” ni Olúwa wí, “nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀. Nítorí pé wọ́n pọ̀ ju ẹlẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye. 24A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti, a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.