Jeremiah 4:27
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Gbogbo ìlú náà yóò sì di ahoro, síbẹ̀ èmi kì yóò pa á run pátápátá.
Jeremiah 4:27 in English
Jeremiah 4:27 · Berean Standard Bible
For this is what the LORD says: “The whole land will be desolate, but I will not finish its destruction.
Context
25Mo wò yíká n kò rí ẹnìkan;
gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ló ti fò lọ. 26Mo bojú wò, ilẹ̀ eléso, ó sì di aṣálẹ̀
gbogbo àwọn ìlú inú rẹ̀ sì ṣubú sínú ìparun
níwájú Olúwa àti níwájú ríru ìbínú rẹ̀. 27Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Gbogbo ìlú náà yóò sì di ahoro,
síbẹ̀ èmi kì yóò pa á run pátápátá. 28Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkún
àwọn ọ̀run lókè yóò ṣú òòkùn
nítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀
mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.” 29Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà
gbogbo ìlú yóò sálọ.
Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó;
ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ.
Gbogbo ìlú náà sì di ahoro;
kò sì ṣí ẹnìkan nínú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.