Jeremiah 31:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó, ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin; Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀, ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.”
Jeremiah 31:22 in English
Jeremiah 31:22 · Berean Standard Bible
How long will you wander, O faithless daughter? For the LORD has created a new thing in the land— a woman will shelter * a man.”
Context
20Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára
tí inú mi dùn sí bí?
Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó,
síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀.
Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un,
èmi káàánú gidigidi fún un,”
ni Olúwa wí. 21“Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde,
ṣe atọ́nà àmì,
kíyèsi òpópó ọ̀nà geere
ojú ọ̀nà tí ó ń gbà.
Yípadà ìwọ wúńdíá Israẹli,
padà sí àwọn ìlú rẹ. 22Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó,
ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin;
Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀,
ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.” 23Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Juda àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan sí i; wí pé, ‘Kí Olúwa kí ó bùkún fún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’ 24Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Juda àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.