Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára tí inú mi dùn sí bí? Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀. Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un, èmi káàánú gidigidi fún un,” ni Olúwa wí.

Jeremiah 31:20 in English

Jeremiah 31:20 · Berean Standard Bible

Is not Ephraim a precious son to Me, a delightful child? Though I often speak against him, I still remember him. Therefore My heart yearns for him;* I have great compassion for him,” declares the LORD.

Context

18“Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé, ‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́ èmi sì ti gbọ́ ìbáwí. Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà, nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi. 19Lẹ́yìn tí èmi ti yípadà, mo ronúpìwàdà, lẹ́yìn tí èmi ti wá mọ̀, èmi lu àyà mi. Ojú tì mí, mo sì dààmú; nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’ 20Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára tí inú mi dùn sí bí? Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀. Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un, èmi káàánú gidigidi fún un,” ni Olúwa wí. 21“Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde, ṣe atọ́nà àmì, kíyèsi òpópó ọ̀nà geere ojú ọ̀nà tí ó ń gbà. Yípadà ìwọ wúńdíá Israẹli, padà sí àwọn ìlú rẹ. 22Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó, ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin; Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀, ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.