Jeremiah 30:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́ láìṣe igbe àlàáfíà.
Jeremiah 30:5 in English
Jeremiah 30:5 · Berean Standard Bible
Yes, this is what the LORD says: “A cry of panic is heard— a cry of terror, not of peace.
Context
3Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.” 4Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda: 5“Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́
láìṣe igbe àlàáfíà. 6Béèrè kí o sì rí.
Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí?
Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin
tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí,
tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora? 7Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó!
Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀,
Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu
ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.