Jeremiah 30:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda:
Jeremiah 30:4 in English
Jeremiah 30:4 · Berean Standard Bible
These are the words that the LORD spoke concerning Israel and Judah.
Context
2“Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan. 3Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.” 4Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda: 5“Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́
láìṣe igbe àlàáfíà. 6Béèrè kí o sì rí.
Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí?
Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin
tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí,
tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.