Jeremiah 3:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé, ‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.
Jeremiah 3:4 in English
Jeremiah 3:4 · Berean Standard Bible
Have you not just called to Me, ‘My Father, You are my friend from youth.
Context
2“Gbé ojú rẹ sókè sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì,
kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò bà ọ́ jẹ́?
Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́,
bí i ará Arabia kan nínú aginjù,
ìwọ sì ti ba ilẹ̀ náà jẹ́
pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti ìwà búburú rẹ. 3Nítorí náà, a ti fa ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn,
kò sì ṣí òjò àrọ̀kúrò.
Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà,
ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú. 4Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé,
‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi. 5Ìwọ yóò ha máa bínú títí?
Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’
Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀
ìwọ ṣe gbogbo ibi tí ìwọ le ṣe.” 6Ní àkókò ìjọba Josiah ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Israẹli aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.