Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò ha máa bínú títí? Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’ Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀ ìwọ ṣe gbogbo ibi tí ìwọ le ṣe.”

Jeremiah 3:5 in English

Jeremiah 3:5 · Berean Standard Bible

Will He be angry forever? Will He be indignant to the end?’ This you have spoken, but you keep doing all the evil you can.”

Context

3Nítorí náà, a ti fa ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn, kò sì ṣí òjò àrọ̀kúrò. Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà, ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú. 4Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé, ‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi. 5Ìwọ yóò ha máa bínú títí? Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’ Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀ ìwọ ṣe gbogbo ibi tí ìwọ le ṣe.” 6Ní àkókò ìjọba Josiah ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Israẹli aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀. 7Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Juda aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.