Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Gbé ojú rẹ sókè sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì, kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò bà ọ́ jẹ́? Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́, bí i ará Arabia kan nínú aginjù, ìwọ sì ti ba ilẹ̀ náà jẹ́ pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti ìwà búburú rẹ.

Jeremiah 3:2 in English

Jeremiah 3:2 · Berean Standard Bible

“Lift up your eyes to the barren heights and see. Is there any place where you have not been violated? You sat beside the highways waiting for your lovers, like a nomad in the desert. You have defiled the land with your prostitution and wickedness.

Context

1“Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn, ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá? Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí? Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́, ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí?” ni Olúwa wí. 2“Gbé ojú rẹ sókè sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì, kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò bà ọ́ jẹ́? Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́, bí i ará Arabia kan nínú aginjù, ìwọ sì ti ba ilẹ̀ náà jẹ́ pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti ìwà búburú rẹ. 3Nítorí náà, a ti fa ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn, kò sì ṣí òjò àrọ̀kúrò. Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà, ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú. 4Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé, ‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.