Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀síwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìtànjẹ ọkàn wọn?

Jeremiah 23:26 in English

Jeremiah 23:26 · Berean Standard Bible

How long will this continue in the hearts of these prophets who prophesy falsehood, these prophets of the delusion of their own minds?

Context

24Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sá pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan, kí èmi má ba a rí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi kò ha a kún ọ̀run àti ayé bí?” ni Olúwa wí. 25“Mo ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’ 26Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀síwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìtànjẹ ọkàn wọn? 27Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sí sin òrìṣà Baali. 28Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.