Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Mo ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’

Jeremiah 23:25 in English

Jeremiah 23:25 · Berean Standard Bible

“I have heard the sayings of the prophets who prophesy lies in My name: ‘I had a dream! I had a dream!’

Context

23“Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí?” ni Olúwa wí, “kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jíjìn. 24Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sá pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan, kí èmi má ba a rí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi kò ha a kún ọ̀run àti ayé bí?” ni Olúwa wí. 25“Mo ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’ 26Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀síwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìtànjẹ ọkàn wọn? 27Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sí sin òrìṣà Baali.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.