Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni Olúwa wí.

Jeremiah 23:28 in English

Jeremiah 23:28 · Berean Standard Bible

Let the prophet who has a dream retell it, but let him who has My word speak it truthfully. For what is straw compared to grain?” declares the LORD.

Context

26Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀síwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìtànjẹ ọkàn wọn? 27Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sí sin òrìṣà Baali. 28Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni Olúwa wí. 29“Ọ̀rọ̀ mi kò ha a dàbí iná?” ni Olúwa wí, “àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú? 30“Nítorí náà, èmi lòdì sí àwọn wòlíì ni,” Olúwa wí, “Tí ń jí ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lò lọ́dọ̀ ara wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.