Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run; kódà nínú tẹmpili mi ni mo rí ìwà búburú wọn,” ni Olúwa wí.

Jeremiah 23:11 in English

Jeremiah 23:11 · Berean Standard Bible

“For both prophet and priest are ungodly; even in My house I have found their wickedness,” declares the LORD.

Context

9Nípa ti àwọn wòlíì èké. Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi, gbogbo egungun mi ni ó wárìrì. Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn, bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa; nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀. 10Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn; nítorí ègún, ilẹ̀ náà gbẹ, àwọn koríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ. Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́. 11“Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run; kódà nínú tẹmpili mi ni mo rí ìwà búburú wọn,” ni Olúwa wí. 12“Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn; níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú. Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,” ni Olúwa wí. 13“Láàrín àwọn wòlíì Samaria, Èmi rí ohun tí ń lé ni sá. Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Baali wọ́n sì mú Israẹli ènìyàn mi ṣìnà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.