Jeremiah 23:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn; nítorí ègún, ilẹ̀ náà gbẹ, àwọn koríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ. Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́.
Jeremiah 23:10 in English
Jeremiah 23:10 · Berean Standard Bible
For the land is full of adulterers— because of the curse, the land mourns and the pastures of the wilderness have dried up— their course is evil and their power is misused.
Context
8Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa ń bẹ tí ó mú irú-ọmọ ilé Israẹli wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.” 9Nípa ti àwọn wòlíì èké.
Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi,
gbogbo egungun mi ni ó wárìrì.
Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn,
bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa;
nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀. 10Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn;
nítorí ègún, ilẹ̀ náà gbẹ,
àwọn koríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ.
Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú,
wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́. 11“Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run;
kódà nínú tẹmpili mi ni mo rí ìwà búburú wọn,”
ni Olúwa wí. 12“Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́,
a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn;
níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú.
Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn,
ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.