Jeremiah 20:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi! Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.
Jeremiah 20:14 in English
Jeremiah 20:14 · Berean Standard Bible
Cursed be the day I was born! May the day my mother bore me never be blessed.
Context
12Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò
tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní,
jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn,
nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé. 13Kọrin sí Olúwa!
Fi ìyìn fún Olúwa!
Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní
lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú. 14Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi!
Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún. 15Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi,
tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé,
“A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!” 16Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú
tí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú
Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀,
ariwo ogun ní ọ̀sán.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.