Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Israẹli jẹ́ mímọ́ sí Olúwa, àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.

Jeremiah 2:3 in English

Jeremiah 2:3 · Berean Standard Bible

Israel was holy to the LORD, the firstfruits of His harvest. All who devoured her found themselves guilty; disaster came upon them,’” declares the LORD.

Context

1Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé: 2“Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé: “Báyìí ni Olúwa wí, “ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ, ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù, nínú ìyàngbẹ ilẹ̀. 3Israẹli jẹ́ mímọ́ sí Olúwa, àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀, gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi, ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. 4Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli. 5Báyìí ni Olúwa wí: “Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi, tí wọ́n fi jìnnà sí mi? Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán, àwọn fúnra wọn sì di asán.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.