Jeremiah 2:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báyìí ni Olúwa wí: “Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi, tí wọ́n fi jìnnà sí mi? Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán, àwọn fúnra wọn sì di asán.
Jeremiah 2:5 in English
Jeremiah 2:5 · Berean Standard Bible
This is what the LORD says: “What fault did your fathers find in Me that they strayed so far from Me, and followed worthless idols, and became worthless themselves?
Context
3Israẹli jẹ́ mímọ́ sí Olúwa,
àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀,
gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi,
ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ”
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. 4Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu
àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli. 5Báyìí ni Olúwa wí:
“Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi,
tí wọ́n fi jìnnà sí mi?
Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán,
àwọn fúnra wọn sì di asán. 6Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà,
tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
tí ó mú wa la aginjù já,
tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò,
ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri,
ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’ 7Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá
láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́,
ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.