Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta? Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù, tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?

Jeremiah 18:14 in English

Jeremiah 18:14 · Berean Standard Bible

Does the snow of Lebanon ever leave its rocky slopes? Or do its cool waters flowing from a distance ever run dry?

Context

12Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ” 13Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: “Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri? Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe. 14Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta? Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù, tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí? 15Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi, wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán, tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn, àti ọ̀nà wọn àtijọ́. Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́, àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe. 16Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di nǹkan ẹ̀gàn títí láé, gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù, wọn yóò sì mi orí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.