Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: “Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri? Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.

Jeremiah 18:13 in English

Jeremiah 18:13 · Berean Standard Bible

Therefore this is what the LORD says: “Inquire among the nations: Who has ever heard things like these? Virgin Israel has done a most terrible thing.

Context

11“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’ 12Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ” 13Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: “Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri? Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe. 14Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta? Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù, tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí? 15Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi, wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán, tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn, àti ọ̀nà wọn àtijọ́. Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́, àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.