Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu.

Jeremiah 17:19 in English

Jeremiah 17:19 · Berean Standard Bible

This is what the LORD said to me: “Go and stand at the gate of the people, through which the kings of Judah go in and out; and stand at all the other gates of Jerusalem.

Context

17Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi, ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú. 18Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi, ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú, jẹ́ kí wọn kí ó dààmú. Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run. 19Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 20Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí. 21Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.