Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí.

Jeremiah 17:20 in English

Jeremiah 17:20 · Berean Standard Bible

Say to them, ‘Hear the word of the LORD, O kings of Judah, all people of Judah and Jerusalem who enter through these gates.

Context

18Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi, ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú, jẹ́ kí wọn kí ó dààmú. Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run. 19Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 20Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí. 21Báyìí ni Olúwa wí, “Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu. 22Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.