Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi, ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú, jẹ́ kí wọn kí ó dààmú. Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.

Jeremiah 17:18 in English

Jeremiah 17:18 · Berean Standard Bible

Let my persecutors be put to shame, but do not let me be put to shame. Let them be terrified, but do not let me be terrified. Bring upon them the day of disaster and shatter them with double destruction.

Context

16Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ, ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú. Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ. 17Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi, ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú. 18Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi, ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú, jẹ́ kí wọn kí ó dààmú. Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run. 19Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 20Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.