Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ, ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú. Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.

Jeremiah 17:16 in English

Jeremiah 17:16 · Berean Standard Bible

But I have not run away from being Your shepherd; I have not desired the day of despair. You know that the utterance of my lips was spoken in Your presence.

Context

14Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn, gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà, nítorí ìwọ ni ìyìn mi. 15Wọ́n sọ fún mi wí pé: “Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà? Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.” Ni Olúwa wí. 16Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ, ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú. Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ. 17Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi, ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú. 18Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi, ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú, jẹ́ kí wọn kí ó dààmú. Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.