Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò fi ara sin lójú mi.

Jeremiah 16:17 in English

Jeremiah 16:17 · Berean Standard Bible

For My eyes are on all their ways. They are not hidden from My face, and their guilt is not concealed from My eyes.

Context

15Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn. 16“Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta. 17Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò fi ara sin lójú mi. 18Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́po méjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì fi òkú àti ohun ẹ̀gbin àti ìríra wọn kún ilẹ̀ ìní mi.” 19Olúwa, alágbára àti okun mi, ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti òpin ayé wí pé, “Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà, ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.