Jeremiah 16:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa, alágbára àti okun mi, ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti òpin ayé wí pé, “Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà, ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.
Jeremiah 16:19 in English
Jeremiah 16:19 · Berean Standard Bible
O LORD, my strength and my fortress, my refuge in the day of distress, the nations will come to You from the ends of the earth, and they will say, “Our fathers inherited nothing but lies, worthless idols of no benefit at all.
Context
17Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò fi ara sin lójú mi. 18Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́po méjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì fi òkú àti ohun ẹ̀gbin àti ìríra wọn kún ilẹ̀ ìní mi.” 19Olúwa, alágbára àti okun mi,
ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú,
àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti
òpin ayé wí pé,
“Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà,
ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀. 20Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́run
fún ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni,
ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run.” 21“Nítorí náà, Èmi yóò kọ́ wọn
ní àkókò yìí,
Èmi yóò kọ́ wọn pẹ̀lú agbára àti títóbi mi.
Nígbà náà ni wọn ó mọ
pé orúkọ mi
ní Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.