Jeremiah 14:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò ojú wọn kò ríran nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”
Jeremiah 14:6 in English
Jeremiah 14:6 · Berean Standard Bible
Wild donkeys stand on barren heights; they pant for air like jackals;* their eyes fail for lack of pasture.”
Context
4Ilẹ̀ náà sán
nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;
ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,
wọ́n sì bo orí wọn. 5Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá
fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,
torí pé kò sí koríko. 6Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo
wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò
ojú wọn kò ríran
nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.” 7Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,
wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ.
Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù,
a ti ṣẹ̀ sí ọ. 8Ìrètí Israẹli;
ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,
èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà
bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.