Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, torí pé kò sí koríko.

Jeremiah 14:5 in English

Jeremiah 14:5 · Berean Standard Bible

Even the doe in the field deserts her newborn fawn because there is no grass.

Context

3Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi, wọ́n lọ sí ìdí àmù ṣùgbọ́n wọn kò rí omi. Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo; ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn, wọ́n sì bo orí wọn. 4Ilẹ̀ náà sán nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà; ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo, wọ́n sì bo orí wọn. 5Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀, torí pé kò sí koríko. 6Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò ojú wọn kò ríran nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.” 7Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa, wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ. Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù, a ti ṣẹ̀ sí ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.