Jeremiah 13:23
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà? Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà? Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere.
Jeremiah 13:23 in English
Jeremiah 13:23 · Berean Standard Bible
Can the Ethiopian * change his skin, or the leopard his spots? Neither are you able to do good— you who are accustomed to doing evil.
Context
21Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ
àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà.
Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ
bí aboyún tó ń rọbí? 22Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè,
“Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀
ni aṣọ rẹ fi fàya
tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe. 23Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà?
Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà?
Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀
náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere. 24“N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbò
tí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́. 25Èyí ni ìpín tìrẹ;
tí mo ti fi sílẹ̀ fún ọ,”
ni Olúwa wí,
“Nítorí ìwọ ti gbàgbé mi
o sì gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run àjèjì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.