Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀ ni aṣọ rẹ fi fàya tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe.

Jeremiah 13:22 in English

Jeremiah 13:22 · Berean Standard Bible

And if you ask yourself, “Why has this happened to me?” It is because of the magnitude of your iniquity that your skirts have been stripped off and your body has been exposed.*

Context

20Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá. Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà; àgùntàn tí ò ń mú yangàn. 21Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà. Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí? 22Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀ ni aṣọ rẹ fi fàya tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe. 23Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà? Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà? Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere. 24“N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbò tí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.