Jeremiah 13:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà. Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ bí aboyún tó ń rọbí?
Jeremiah 13:21 in English
Jeremiah 13:21 · Berean Standard Bible
What will you say when He sets over you close allies whom you yourself trained? Will not pangs of anguish grip you, as they do a woman in labor?
Context
19Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa,
kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn.
Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,
gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá. 20Gbé ojú rẹ sókè,
kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá.
Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà;
àgùntàn tí ò ń mú yangàn. 21Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ
àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà.
Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ
bí aboyún tó ń rọbí? 22Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè,
“Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀
ni aṣọ rẹ fi fàya
tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe. 23Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà?
Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà?
Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀
náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.